ǸJ OHUN EGAN NI BÍ A BÁ WÍPÉ JÉSÙ NÌKAN NI ỌNÀ?

LÁTI ỌWỌ RYAN LEASURE

 

Ǹjẹ́ ohun ẹgàn tàbí ìjọra-ẹni-lójú ni lati wípé Jésù nìkan ni ọna ìgbàlà? Charles Templeton rò bẹ́ẹ, ó wí pé :

 

“Àwọn Kristẹni je àkójọ tí ó kére nínú ayé. Ó kéré jù, ìdá mérin nínú márùn-ún gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run mìíràn tí ó yàtọ sí Ọlọ́run Kristẹni, ìdá ènìyàn bilionu márùn-ún tí ó wà ní ayé ń bọ jùọọ́dúnrún olorun lọ.

 

Bí a bá fi ẹsin ìgbàgbọ́ nínú ẹranko àti èmí tàbí ẹsin ẹ̀yà sínú rẹ, ó ju iye yìí lọ. Ǹjẹ́ a leè gbàgbọ́ wípé àwọn Kristẹni nìkan ni ó wà lójú ọ̀nà òtítọ́? Kini kí a ti wí sì ohun tí Templeton sọ yìí? Ǹjẹ́ o je ohun ailoye bí a bá wí pé Jésù nìkan ni ọna ìgbàlà òtítọ́? Tàbí ẹwẹ̀, ǹjẹ́ Kristẹni jẹ̀bi “atileyin èrò ìgbàgbọ́ àìlóye”? Bí àwọn kan ti wí.

 

Àwọn igbedeke jẹ́ ìpìlẹ ìdí ọpọ esin – ìgbàgbọ́ wípé bákan náà ni gbogbo ẹsin rí, bẹ́ẹ̀ ni wọn ń tọ́ka sí Ọlórun kan náà.

 

Nínú àṣà tó fi ààyè gba èrò afójú òtítọ́, ǹjẹ́ kí àwọn Kristẹni gba ikilọ àwọn ọlọ́pọ̀ ẹsin kí wọn sì dẹ́kun ẹ̀kọ́ wípé Jésù nìkan ni ọna. Mí ó rò bẹ́ẹ̀ fún àwọn ìdí kan. Àkọ́kọ́, ọ̀pọ̀ ẹsin jẹ́ èrò tí ó ń já ‘ni ku’lẹ. Kò lè fìdí múlẹ bí a bá ṣàgbéyẹ̀wò òye. Èkejì, ọ̀pọ̀ ẹsin fi ojú fò ìmò sayensi àti ìwádìí ìṣẹlẹ. Ẹ jẹ kí a ṣàgbéyèwò wọn lọ kọ̀ọ̀kan.

 

ỌPỌ – ẸSÌN Ń JÁ’NI KU’ LẸ̀

 

Láti gbé èrò wọn lárugẹ, àwọn ọlọ́pọ ẹsìn sọ òwe àwọn afójú ọkùnrin àti erin. Òwe náà lọ báyìí :

“Àwọn afójú ọkùnrin márùn-ún kan wà tí wọn pàdé erin kan ní pápá. Ọkùnrin afọ́jú àkọ́kọ́ gbá irú rẹ̀mú, ó wí pé ,” ah, òkun ni.” Ọkùnrin afójú èkejì, fọwọ́ kan ẹsẹ̀ kan, ó wí pé , ” rárá, igi ni. ” ẹ̀kẹta gba imú rẹ mú, ó wí pé, ” rárá ejò ni. “, ekerin gbá ìho kan mú, ó wí pé, “rárá o, idà ni” ekaarun fi ọwọ kan ara rẹ, “ó wí pé ” rárá, ògiri ni”.

 

Àwọn ọlọ́pọ ẹsin náà gbàgbó wípé àwọn afọ́jú ọkùnrin náà dabi gbogbo ẹsin ayé ni.

Ẹsìn kọọkan ni igbàgbó àìmọ̀ wípé èrò wọn nípa ayé ni ó tọ̀nà. Ṣùgbọ́n ní igbẹyin, gbogbo wọn ni ó ṣìnà. Bákan náà ni gbogbo ẹ̀sìn rí, wọ́n sì ń tọ́ka sí ibì kan. Kò sí ‘ọna òtítọ́’ kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́pọ ẹsìn tí gbàgbọ́.

 

ÀWỌN ẸSÌN Ń TAKO ARA WỌN.

Nígbà tí àwọn ọlọ́pọ̀ ẹ̀sìn fẹ́ràn láti wí pé bákan náà ni gbogbo ẹsin rí, kò jìnnà sí òtítọ́, fún àpẹẹrẹ ìṣẹ̀dá Ọlọ́run nínú àwọnkókó ẹ̀sìn. Àwọn ẹlẹ́sìn tí India gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run púpọ tí ìṣẹ̀dá wọn jẹ́ ọ̀kan. Àwọn onígbàgbó ère, bí wọn ṣe jẹ́ ẹni ẹ̀mí tó, kìí sìn Ọlọ́run kankan, ẹkọ́ èmi ti ìgbàlódé kọ́’ni wípé kí oníkálukú rí ara rẹ̀ bí Ọlọ́run kékeré.

 

Ẹṣin Isilaamu gbàgbó nínú Ọlórun kan tí wón ń pè ní Allah tí ó ní agbára lórí gbogbo ìṣẹ̀dá. Àwọn onigbagbọ Júdà gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run alágbára kan tí wọn ń pè ní Jèhófà.

Ẹsìn ìgbàgbọ́ kọ́’ ni pé Jésù jẹ́ alailẹ́gàn, ó kú ní orí igi àgbélébùú, ó jí dìde kúrò nínú òkú.

 

Bí ayé bá wà, mo lè tẹ síwájú láti ṣàlàyé bí àwọn ẹsin wonyii ṣe yàtò lórí ìṣẹ̀dá, ìwé-mimọ, ìṣẹ̀dá ènìyàn, ẹṣẹ̀, ìgbàlà, àti ìyè àìnípèkun. Ní èdè mìíràn, àwọn ẹsin, wonyii fẹẹ má fi ibì kankan jọ’ra.

 

ỌPỌ̀ ẸSÌN ṢÀLÀYÉ ÒYE

 

Kò bá òye mú bí a bá wí pé gbogbo ẹsin ni ó ń kọ ohun kan náà. Fún àpẹẹrẹ, esin Kristẹni kọ́ wípé mẹ́talọ́kan ni Ọlórun. Síbẹsibe, Ọlọ́run kò lè jẹ mẹ́talọ́kan nínú ẹṣin Kristẹni kí ó má rí bẹ́ẹ nínú àwọn ẹṣin tó kù.

 

Èyí yóò rú òfin alaitako ohun kan kò lè jẹ méjì lẹẹkan náà àti ní ọnà kan náà. Bí a bá wípé gbogbo ẹsìn ni ó tọ́ nípa ìṣẹ̀dá Ọlọ́run, èyí ru òfin ìpìlẹ ti òye.

 

Tàbí bí a bá wo ìṣẹ̀dá Jésù, kò lè tọ̀nà wípé Jésù ni Ọlọ́run (nínú ẹṣin Kristẹni) kí ó má rí bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ẹṣin tó kù lẹ́ẹ̀kan náà àti ní ọ̀nà kan náà. Èyí yóò tako òfin ìpìlè tí aláìtakò.

 

ỌPỌ ẸSÌN NÁÀ MÁA Ń DÁ ÈRÒNGBÀ NI

 

Ní ọ̀nà tí a lè má lé’rò, ọ̀pọ̀ ẹṣin máa ń dá erongba ní, wọn gbàgbọ́ wípé òtítọ́ ni ọ̀pọ̀ ẹsin, nígbà tí èrò àwọn ẹṣin tó kú jẹ́ èké. Èyí túmọ̀ sí wípé àwọn ọlọ́pọ̀ ẹ̀sìn náà jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn esin mìíràn. Nígbà tí ọ̀rọ̀ tí rí báyìí, ǹjẹ́ ó tọ̀nà bí a bá wípé àwọn ọlọ́pọ̀ ẹsin ń pẹ̀gàn nígbà tí wọ́n wípé ìmọ̀ wọn nípa òtítọ́ ni ó tọ̀nà tí àwa àwa ẹlẹ́sìn tó kù jẹ́ alaimokan?

 

ỌPỌ ẸSÌN FI OJÚ FO ÀWỌN KÓKÓ ÌWÁDÌÍ ÌṢẸLẸ̀ ÀTI ÌMỌ̀ SÁYẸ́NSÌ

 

Báyìí, ohun kan ní láti sọ wípé gbogbo ẹsin kò lè jẹ́ òtítọ́, ohun mìíràn ni lati sọ wípé ọ̀kan nínú wọn ni òtítọ́. Ṣùgbọ́n àwọn ẹri tó dájú ń tọ́ka sí ona ẹṣin Kristẹni.

 

ẸRÍ ÌMỌ SÁYẸ́NSÌ

 

Ẹ ṣàgbéyẹ̀wò orísun àgbáyé. Gbogbo ìwádìí ìmò sayensi ń tọ́ka sí wípé ààyè, àkókò àti ohun aridimu, gbogbo wọ̀nyí dí wíwà ní ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn.

Tí ó túmọ̀ sí pé Aṣẹ̀dá ayé gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí a kò lè gbá mú, àìlópin, àti èyí tí a kò lè rí.

Èyí ṣe rẹ́gí nínú ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn Kristẹni wípé Ọlọ́run dá ayé láti inú òfo ṣùgbọ́n ó tako ẹ̀sìn tí ó ń bọ ìṣẹ̀dá ayé, bí èyí tí ó gbàgbó nínú ohun tí ó tako èṣìn Kristẹni.

 

Ẹrí ìmọ̀ sayensi fí àwọn ẹsin ti o gbàgbó nínú Ọlọ́run kan ṣe àpẹẹrẹ. Síbẹ̀, bí a bá ṣe àkíyèsí Jésù Kristi ti Násárétì, esin Kristẹni tayọ.

 

ẸRÍ ÌWÁDÌÍ

 

Fún àpẹẹrẹ, àwọn oluwadii tí lailai fi ìmọ̀ sokan wípé Jésù Kristi ti Násárétì kú lórí igi àgbélébùú ni atetekose. Ẹsin Isilaamu tako èyí wípé a kàn Jésù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn wòlíì Ọlórun mọ́ igi. Nígbà tí àwọn ọpọ onímọ ìjìnlẹ̀ nínú ìwádìí fi hàn pé òtítọ́ ni, a lè sọ pé esin Isilaamu kò yege gẹ́gẹ́ bí ẹsin kan tí ó tọnà.

 

Ní pàápàá, ikanmogi Jésù dájú débi wípé onímọ nípa ohun tí ó rújú; John Dominic Crossan gbà wipe ìkànmọ́gi Jésù láti ọwọ́ Pontiu Pílátù dájú gbangba.

 

Pẹlú ọnà mẹta péré, a dá àfojúsùn wá padà sórí àjíǹde. Ǹjẹ́ Jésù jí dìde kúrò nínú òkú, bí ó bá rí bẹ́ẹ, òtítọ́ ni ẹsin Kristẹni yàtọ sí àwọn ẹsin mìíràn. A ní àwọn ìdí púpọ̀ láti gbàgbọ́ wípé òtítọ́ ni. Ẹ jẹ ki n fún wa ní àwọn àpẹẹrẹ méjì ni ṣókí.

 

Àkọ́kọ́, àwọn Kristẹni gbà pé àwọn obìnrin ni ó kọ́kọ́ rí ìṣẹlẹ àgbàyanu yìí. Nínú àṣà ti kò fi bẹ́ẹ ká ọrọ obìnrin si, ó nira láti gbàgbó wípé àwọn Kristẹni fi èyí pa irọ́, nígbà tí èyí kò lè rí bẹ́ẹ, a ní ìdí tó dára láti wípé èyí fi ohun tí ó ṣẹlẹ hàn.

 

Ní àfikún, àwọn ọmọ èyìn tó sún mọ́ Jésù jùlọ ṣe tán láti fi ẹmí wọn lélẹ̀ fún ìgbàgbọ́ àjínde Jésù. Ǹjẹ́ a kò lérò wípé ó kéré jù, ọkan nínú wọn ì bá bẹ̀rù ibenilori àti ikú kì ó wí pé irọ́ ni gbogbo rẹ

 

Bí a bá rántí pé àwọn ọmọ èyìn wọnyi kan náà ni ó ṣe ojo nígbà tí wón mú Jésù fún ìkànmọ́gi.

Bí Jésù bá jí dìde kúrò nínú òkú, èyí jásí wípé òtítọ́ ni ohun tí ó sọ – Òun ni Ọlórun, Òun nikan ni ọna òtítọ́ fún ìgbàlà.

 

ǸJẸ́ Ẹ̀GÀN NÍ BÍ A BÁ WÍPÉ JÉSÙ NÌKAN NI ỌNÀ?

Mi ò mọ ẹnikẹ́ni tí ó lè sọ wí pé Jésù Kristi ti Násárétì jẹ́ ẹlẹ́gàn. Idakeji ni wọn máa ń sọ. Ó jé ẹni mímọ gidigidi. Bẹẹni, Jésù yìí kan náà ni ó wí pé òun ni ọna òtítọ́ àti ìyè, kò sí ẹni tí yóò wá sọ́dọ̀ baba bikose nípasẹ̀ mi. (Jòhánù 14:6).

 

Bí a ṣe ń rònu sì ìbéèrè yìí, ẹ jẹ kí a wo ọrọ̀ yìí láti ẹnu sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ àti ẹni tí kò gbà pé Ọlọ́run wà ; Penn Jillette:

“Mo máa ń sọ pé mi ò bọwọ fún àwọn tí kò ń kéde ẹsin wọn rárá, bí o bá gbàgbó wípé bí ọrun rere ṣe wá bẹẹ ni ọrùn àpáàdì wà, tí ó sì ṣeé ṣe kí àwọn ènìyàn lọ sí ọrun àpáàdì tàbí kí wón má ni ìyè àìnípèkun, tí ó sì lérò wípé kò tọnà láti sọ èyí fún wọn kí wón lè níyì ní àwùjọ, àti àwọn tí kò gbàgbọ́ nínú Ọlórun àti ìkéde ẹsin, báwo ni a ó ṣe korira ènìyàn tó ti a kò ní kéde ẹsin tàbí kí ó gbàgbọ́ pé ìyè àìnípèkun see ṣe tí o kò sì sọ èyí fún wọn?

 

Àní, bí ó bá hàn sí mi gbangba pé ọkọ kan fẹ rọ́ lù ọ́, ṣùgbọ́n tí o kò gbà èyí gbọ́, èyí lè fà kí a ní àríyànjiyàn, èyí sì ṣe pàtàkì jùlọ.

Ǹjẹ́ ohun ẹgàn ni láti sọ fún àwọn ènìyàn wípé Jésù nìkan ni ọna? Mo wí fún wa lóòótọ́ lóòótọ́ wípé ohun tí ó dára púpọ ni láti ṣe.