Lati ọwọ: Melissa Dougherty
Ọpọlọpọ àwọn ènìyàn máa ń rí “àìdọgba dàpọ” nínú Bíbélì tàbí gbó ó nínú itakurọsọ tí wọn sì ni èrò kan tàbí òmíràn nípa rẹ: (1) KÌ ń ríi dájú pé mo fi idọgba dàpọ pẹlu olólùfẹ mi, tàbí (2) kilode tí Poolu fi ń ṣàníyàn nípa tinú ẹyin ènìyàn, débi pé kí wọn dọgba?
Bí ó ṣe ṣe pàtàkì tó láti jẹ oúnjẹ asaraloore tó, ẹsẹ yìí kò níí ṣe pẹlu adiyẹ. Ó sì yà awọn ènìyàn lenu pé ko pín sí ìgbéyàwó nìkan. Mo fe láti tú èyí pale sii.
Kini àjàgà gan-an?
Àjàgà jẹ ẹrù onigi tí ó ń sọ ẹranko nla méjì papọ, bíi kẹtẹkẹtẹ, ó sì máa ń rán wọn lọwọ láti sise bákan náà papọ. Wọn máa ń gbé àjàgà isẹ papọ. A máa ń so ó mọ ohun irinsẹ tàbí igi, wọn si maa fà á leekan náà gege bí okan. Wọn jọ ń sise pọ ni. Njẹ pẹlu èyí ni ọkàn, ẹ jẹ ká ka ẹsẹ Bíbélì yii:
“Ẹ má ṣe fí àìdọgba dàpọ pẹlú àwọn aláìgbàgbọ: nítorí idápọ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdápọ kín ni ìmọlẹ sì ní pẹlú òkùnkùn?. Ìrẹpọ kín ni Kírísítì ní pẹlú Bélíàlì? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọní pẹlú aláìgbàgbọ? Ìrẹpọ kín ni tẹḿpìlì Ọlọrun ní pẹlú òrìṣà? Nítorí ẹyin ní tẹḿpìlì Ọlọrun alààyè; gẹgẹ bí Ọlọrun ti wí pé, Èmi á gbé inú wọn, èmi o sì máa rìn láàárin wọn; èmi ó sì jẹ Ọlọrun wọn, wọn yóò sì jẹ ènìyàn mi. Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàárin wọn, kí ẹ sì yá ara yín si ọtọ, ni Olúwa wí. Ki ẹ má ṣe fi ọwọ kan ohun àìmọ; Èmi ó sì gbà yín. Èmi o sì jẹ Baba fún yín, Ẹyin ó sì jẹ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi! ní Olúwa Olódùmarè wí.” (2 Kor. 6:18-18) (ESV).
Pẹlu alaye “dapọ”, ẹ wo òye kẹtẹkẹtẹ tí ó dapọ yìí, ẹ wo bí wọn kò bá dọgba, bí okan lara wọn kò bá dọgba, tí kò sì dúró deede, èyí yóò mú kí ọkọ náà ma dúró deede, tí àwọn kẹtẹkẹtẹ tó kù kò ní lè sise papọ. Èyí yóò mú kí wọn máa pooyi tàbí dúró lójú kan. Mo tún gbà èrò yìí nipa idije elese mẹta tí a sọ ẹsẹ àwọn ènìyàn papọ, sugbọn lona tí kò tọ, tí wọn kò sì lè ṣíṣe papọ de ìparí ìlà, tí enikan kọ láti gbéra, tàbí kí a sọ wọn pò lona aitọ, tí wọn kò sì lè rìn nitori rẹ. Tí enikan ń fà àwọn yòókù bí àpò àpáta, tí ó ń gbìyànjú láti tesiwaju sugbọn ti ko lágbára rẹ.
Kíni afiwe yìí jẹ́?
Gege bí ese miran ninú, ó máa ń ṣeni láǹfààní láti mọ onkọwe, ìdí tí ó fi ń kọ ọ, àti ẹni tó ń kọ ọ sí. Pọọlu ń kó ìwé sì ìjọ awọn ará Kọrińtì láti gbé àṣẹ rẹ nija àti láti bá àwọn tó ń yí òtítọ pò wí. Poolu soro lori èyí ni ori kẹfà (6), ó ṣòro lórí igbagbọ àwọn ará Korinti tí ó fi igbedeke sí.
Pọọlu feran àwọn ará Korinti, ó sì fẹ́ kí wón mọ èyí. Ní orí kẹfà 6:11-13. Ó wípé, wọn ni ìrora ọkàn nípa rẹ, sugbọn ó wí pé, rárá, mi ò fún yín ní igbedeke, ó wípé ara wọn ní wón ń fún ní igbedeke, nípa ifẹ ayé àti ìgbéraga ọkàn.
Èyí jẹ ohun ti a mọ, àbí? A ń rí èyí lónìí, nígbà tí àwọn ènìyàn ro pe kò “dára” tàbí ó jẹ “idanilẹjọ” láti soro nípa igbedeke ìwà.
Bí èyí ṣe ń kín àwọn ẹsẹ nípa fífi aidọgba dapọ lẹyin, a lè ní ìyè sii nípa ìdí tí Pọọlu fi fi èyí ṣe àpẹrẹ. Pọọlu ń ṣòrọ lórí àwọn ifẹ aniju àwọn Kristẹni Korinti. Wọn ti dá ara wọn pò – fi aidọgba dapọ – pẹlu awọn alaigbagbọ, tí ó dènà irẹpọ wọn pẹlu Pọọlu. Pọọlu ń wí pé kí wọn má ṣe dapọ ni ọna yìí nítorí pé ó pá ibasepọ wọn pẹlu Ọlọrun àti àwọn onigbagbọ mìíràn lara. Ọrọ nípa “má ṣe fi aidọgba dapo” dá lórí Deuteronomy 22:9, tí ó lòdì sí sísọ àwọn ẹranko méjì ọtọtọọ papọ. Ó ń ṣòrọ nípa sísọ àwọn nǹkan tí kò yẹ papọ. Bii idapọ àwọn oúnjẹ tàbí ohun elo tí kò bára mú.
Opo eniyan maa n ló ẹsẹ yìí bí wọn ba n sọrọ nípa fifẹ alaigbagbọ, tí ó sì jẹ otito, sugbon Pọọlu ń ṣòrọ julọ nípa ìyẹn nìkan. Ó tọka sí ibikíbi tí a bá gba kí ayé kò wá ní pápá mora débi tí a máa ṣe iyèméjì igbagbo wa tàbí gba ọpọ igbagbọ àwọn mìíràn. Ní èdè mìíràn, ó jẹ “bíbá ayé rẹ”, bí a ti kà nínú Roomu 12:2.
[Akiyesi] “aidọgba dapọ” ń tọka sí ibikíbi tí a bá gba kí ayé kò wá ní pápá mora débi tí a máa ṣe iyèméjì igbagbo wa tàbí gba ọpọ igbagbọ àwọn mìíràn”. [Akiyesi]
NÍ odi kejì, àwọn miran máa ń lọ ẹsẹ yìí láti sọ pé kí a má ṣe ní nkan ṣe pẹlu awọn ti igbagbo wọn yatọ si tiwa, èyí kò sì je òtító. Jésù pàápàá kò ṣe èyí. Ohun tí Pọọlu kò sọ ní pé kí a má bá àwọn alaigbagbọ ṣe. Erongba náà ni lati gbe inú ayé sugbọn kí a má jẹ ti ayé, a ó dà wá láti wá fún ẹsin nikan, nipa bíbá àwọn tó gbọ tiwa nìkan ṣe. Èyí kò bá Bíbélì mú, bẹẹni kò tẹle asẹ Bíbélì láti mú kí àwọn ọmọ èyìn Matt. 28 tàbí láti mọ ohun tí a gbagbọ àti ìdí tí a fi g a a gbọ, bí ó ṣe wá nínú 1 Pet. 3:15. A ń gbé imole wá pamọ sì abé igbó, Jésù sì rọ wá kí a má ṣe èyí, a gbodo je ki o tàn. Èyí kò túmọ sì pé bí a bá ní ẹri ọkàn kíkú, tàbí bí a bá feran láti máa tẹ àwọn ènìyàn lọrun, kí a wá fi ara wa si ipo ẹmi tó léwu. A ní láti ni imọ òye ẹmí kí a sì ni òye wọn. Sugbọn èyí kò sọ pe a ní láti máa kẹgan àwọn alaigbagbọ tàbí kí a jẹ gàba lórí wọn nípa lílo ese yìí gẹgẹ bí aridimu láti má bá àwọn tí ó ní òye tó yàtò sì tiwa ṣe tàbí kí a máa pẹgan àwọn Kristẹni tí wọn ba se oyaya tàbí dára sí àwọn alaigbagbọ.
Èyí kò bá Bíbélì mú, kò sì dára fún ìlera ni èrò tèmi.
Àní, níbi, a ń sọrọ nípa… Àwọn kan gbé àjàgà aile seese lórí àwọn míràn, àjàgà tí Jésù wà láti gba kuro. Wọn máa ń lọ ese Bíbélì yìí ni ọna aloju, gẹgẹ bí ohun ìjà, sì àwọn ẹgbẹ wọn nínú Olúwa pàápàá. Kiise láti tẹ wọn lọrun, wọn ń sì koko ẹsẹ yìí.
Ṣùgbọ́n njẹ kò jẹ ohun ifẹ láti pín nínú àjàgà wọn?
Ìyàtò tó wà níbi ni ise pelu awon igbedeke kan. Àwọn Kristẹni Korinti gbèrò pé, jù bí àwọn ènìyàn ń ṣe lónìí, pé ó jẹ ” ohun ifẹ” láti gba ese àwọn ènìyàn pẹlu òdodo, òkùnkùn pẹlu imọlẹ, esu pẹlu Kristi. Nígbà tí Pọọlu wí pé kí a má ṣe fi aidọgba dapọ, mo fé ro èyí gẹgẹ bii tí ìlànà àtijọ tí ajọwa tàbí tí amumọra. Má jẹ ti ajọwa, óò lè fi ìfẹ Ọlọrun kún un, lai bá ibi wí.
Àpẹrẹ tó tọnà jù fún alaye ohun tí Pọọlu ń sọ níbi ni lati ṣàkíyèsí ìwà àwọn Kristẹni Korinti pé kí a rí í pé ó ń sọ pé wọn ronú bí àwọn tí ayé, kii se bí àwọn ẹni bí Ọlọrun. Nítorí apejọpọ aiwa bí Ọlọrun tí kò dára wọn, ó mú kí wọn kọsẹ kí wọn sì dẹsẹ. Pọọlu ń ṣe àtúnṣe èyí, ó sì ń gbìyànjú láti fi irẹpọ sì àárín wọn.
Didapọ pẹlu ènìyàn tumọ sì pé ó wà nínú ibasepọ tí kò daju pẹlu wọn, àti pé ó ń fi igbagbọ rẹ sábẹ ewu láti ṣe é. Ó jé irufẹ orísìí igbagbo. Èyí ni dida eko Kristẹni pọ mọ igbagbọ àṣà tí wọn tẹwọgba layíká rẹ tí ó sì ń bí àdàlù ẹṣin Kristẹni tí ó dàbí pé ó ṣíṣe fún gbogbo ènìyàn. Sugbọn ni tootọ, nitori ki o mà bàa ṣẹ àwọn ènìyàn ní àyíká rẹ ni. Ẹ ṣàgbéyèwo èyí pẹlu alaye igbelewọn, tí ó jẹ èyí tí a fẹ ṣe nígbà tí a bá ń tàn ìhìn rere kalẹ ni ọna tó bá àṣà àwọn alaigbagbọ mú nígbà tí a kò fi òtító ìhìn rere láti tú àwọn ènìyàn àti asa lójú.