Àwọn ìdí márùn-ún tí Idà Ọgbọn Àwọn Akẹkọọ kò fi fi ìjọ silẹ

 IjọAwọnỌmọẸyìn 

 

Lati ọwọ Jason Jimenez  

Gẹgẹ bí àṣà àwọn Amerika ṣe ń dàgbà sii  nínú aye, àwọn ìjọ kò ńí irú agbára ìdarí àti ipa tí wọn tí ni rí. Ijọ kò jẹ babara fún ọpọlọpọ àwọn ọdọ Amerika mọ, ọpọ nínú àwọn Kristẹni ni kò gbà èrò láti fi gbongbo lélẹ nínú ìjọ.  

 O lè jẹ ohun ìyàlénu pé àwọn ọdọ tí àwọn ọdọ tí ó di ní ìjọ ní ọkàn sì wà, àti pé igbagbọ ohun tó ṣe pàtàkì julọ ninu ayé wọn. Èyí wù ni lórí, ó sì jẹ ohun ìdùnnú.  

Nítorí náà, dípò ifilọ nípa àwọn iwadii búburú àti ohun tó báni nínú jẹ nípa àwọn odọ kékeré àti àwọn ọdọ lángba,, mo lérò pé ó ṣe pàtàkì kí n sọ àwọn ìdí márùn-ún to ń wù ni lórí tó bí àwọn idà ọgbọn àwọn ọdọ Kristẹni sì fi fidimulẹ nínú ìjọ.  

ÌDÍ KÍNNÍ :WỌN NÍ IBASEPỌ TO GUNMỌ PẸLU JÉSÙ  

Ọpọlọpọ àwọn ọdọ tí wọn tọ ninu ìjọ, yálà pé wọn kò tíì ṣe ìjẹwọ igbagbọ to dájú, tàbí wọn kò tilẹ gba ẹkọ ọmọ ẹyin láti ọwọ àgbàlagbà Kristẹni. Àwọn idá ọgbọn Kristẹni tó dantọ yìí nínú ìjọ ní o ni ibasepọ to dán mọran pẹlu Jésù. Si awon wonyi, wọn ríi gẹgẹ bí igbe ayé Kristẹni gẹgẹ bí ibasepọ, kii se ẹṣin. Wọn ò lọ ìjo nítorí awọn òbí wọn ṣe bẹẹ. Wọn ń lọ nítorí pé wọn fẹ láti dàgbà nínú igbagbọ wọn pẹlu awọn Kristẹni bíi tiwọn.  

IDI KEJÌ:  WỌN FẸ LÁTI NÍ ÌMỌ NÍPA BÍBÉLÌ  

Àwọn ọdọ Kristẹni wọnyí ni ipongbẹ ńlá láti kọ nípa ohun tí wọn gbagbọ ati lati se ohun ti Bíbélì wí. Ẹsẹ ńlá tí ó sọ èyí ni Jakobu (1:22), tí ó wí pé, “Ẹ maa kan jẹ olùgbọ ọrọ naà lásán, kí ẹ má baà tipa èyí tan ara yín jẹ. Ẹ ṣe ohun tí ó sọ.” (NIV). Àwọn ọdọ wonyi ko wa fún itanjẹ, sugbọn láti mọ ifẹ Ọlọrun fún ayé wọn. Wọn sì mọ pe Bíbélì ni àwọn ìdáhùn tí wọn lé gbẹkẹle.  

ÌDÍ KẸTA : ÀWỌN ÒBÍ TÓ MỌ PÀTÀKÌ ÌJỌ NÍ Ó TỌ WỌN  

Gégé bí olùṣọ àgùntàn, àti bàbà fún àwọn ọmọ mẹrin, èmi àti ìyàwó mi ti ní ẹri aridaju nípa ipa tí ìjọ kó nínú ayé àwọn ọmọ wa. Nígbà tí àwọn òbí bá fi ọwọ gidi mú ìjọ, ó má ń kọ àwọn ọmọ wọn láti má sọ ọ nù. Fún àwọn ọdọ Kristẹni yìí, bí ìjọ ṣe jẹ ohun iyebíye fún wọn, bẹẹ  náà ni ó jẹ ilé fún wọn. Fún wọn, ìjọ je ibi ti wọn gbójúle láti sọ ọrọ òtítọ sínú ayé wọn, àti láti mú àwọn ebun ẹmi wọn dàgbà. Njẹ, ẹ Kúuṣẹ, bàbà àti ìyá, bí ẹ ṣe ń kọ àwọn ọmọ yín ní pàtàkì ìjọ.  

 

 

ÌDÍ KẸRIN : WỌN NÍ ÀWÙJỌ NÍNÚ ÌJỌ WỌN  

Ọnà idamọ igbagbọ fún ọdọ tóbi gidigidi! Àwọn ibadepọ tó ní itumọ jẹ abala pàtàkì nínú àṣeyọrí àti iserere ọdọ. Láìsí àwùjọ, ó seese kí àwọn ọdọ yapa kúrò nínú ìgbàgbọ, kí wọn sì bára we inú ọpọlọpọ àwọn nkan ti won ó padà kabamọ. Fún ìdí èyí, ohun kan tí a rí nípa àwọn idà ọgbón àwọn amagagbona ni òtítọ àti òdodo wọn sì àwùjọ to fese múlẹ.  

ÌDÍ KARÙN-ÚN: WỌN FẸ́RÀN LÁTI SÌN 

Ìdí tó gbeyin tí a ṣàkíyèsí pé ó ń fà ikopa wọn nínú ìjọ ni èmi àfojúsùn. Sísìn àwọn miran nínú ijọ máa ń fún àwọn ọdọ ni ẹmi asepe. Mo rántí akẹkọkọ kan tó ń sọ fún mi nínú ìpàdé kan pé sisin àwọn mìíràn nínú ìjọ má ń fà òun sunmọ Kristi. Mo sì gbà èyí gbọ!  

Njẹ, ẹyin òbí, ó yẹ kí ẹ mọ pe àwọn ọdọ Kristẹni sì kù tí wọn ń sìn pẹlú òtítọ nínú ijọ; a ní láti pelu wọn nínú àdúrà pé Ọlọrun yóò lo wọn láti kéde ìhìn rere Jésù Kristi fun àwọn ìran wọn.  

Nípa Onkọwé: Jason Jimenez jẹ Olùdarí isẹ ìránṣẹ́ STAND STRONG àti onkowe Challenging Conversations:  Itọnisọna  lórí àwọn ọrọ to ṣe kókó nínú Ìjọ.  Fún alaye lẹkunrẹrẹ, wo www.standstrongministries.org. 

Àwọn ètò tí a là kalẹ : 

Orísun : http://bit.ly/3ZT4Scq